27. Nikẹhin gbogbo wọn, obinrin na kú pẹlu.
28. Njẹ li ajinde oku, aya ti tani yio ha ṣe ninu awọn mejeje? nitori gbogbo wọn li o sá ni i.
29. Jesu dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ṣìna, nitori ẹnyin kò mọ̀ iwe-mimọ́, ẹ kò si mọ̀ agbara Ọlọrun.
30. Nitoripe li ajinde okú, nwọn kì igbeyawo, a kì si fi wọn funni ni igbeyawo, ṣugbọn nwọn dabi awọn angẹli Ọlọrun li ọrun.
31. Ṣugbọn niti ajinde okú, ẹnyin kò ti kà eyi ti a sọ fun nyin lati ọdọ Ọlọrun wá wipe,
32. Emi li Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu? Ọlọrun ki iṣe Ọlọrun awọn okú, bikoṣe ti awọn alãye.