23. Ni ijọ kanna li awọn Sadusi tọ̀ ọ wá, awọn ti o wipe ajinde okú kò si, nwọn si bi i,
24. Wipe, Olukọni, Mose wipe, Bi ẹnikan ba kú li ailọmọ, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o le gbe irú dide fun arakunrin rẹ̀.
25. Awọn arakunrin meje kan ti wà lọdọ wa: eyi ekini lẹhin igbati o gbé aya rẹ̀ ni iyawo, o kú, bi kò ti ni irúọmọ, o fi aya rẹ̀ silẹ fun arakunrin rẹ̀:
26. Gẹgẹ bẹ̃li ekeji pẹlu, ati ẹkẹta titi o fi de ekeje.
27. Nikẹhin gbogbo wọn, obinrin na kú pẹlu.
28. Njẹ li ajinde oku, aya ti tani yio ha ṣe ninu awọn mejeje? nitori gbogbo wọn li o sá ni i.