Ninu awọn mejeji, ewo li o ṣe ifẹ baba rẹ̀? Nwọn wi fun u pe, Eyi ekini. Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, awọn agbowode ati awọn panṣaga ṣiwaju nyin lọ si ijọba Ọlọrun.