Jesu si wọ̀ inu tẹmpili Ọlọrun lọ, o si lé gbogbo awọn ẹniti ntà, ati awọn ti nrà ni tẹmpili jade, o si yi tabili awọn onipaṣiparọ owo danù, ati ijoko awọn ti ntà ẹiyẹle.