17. Lõtọ ni mo sá wi fun nyin, ọ̀pọlọpọ wolĩ ati olododo ni nfẹ ri ohun ti ẹnyin ri, nwọn kò si ri wọn; nwọn si nfẹ gbọ́ ohun ti ẹ gbọ́, nwọn ko si gbọ́ wọn.
18. Nitorina ẹ gbọ́ owe afunrugbin.
19. Nigbati ẹnikan ba gbọ́ ọ̀rọ ijọba, ti kò ba si yé e, nigbana li ẹni-buburu ni wá, a si mu eyi ti a fún si àiya rẹ̀ kuro. Eyi li ẹniti o gbà irugbin lẹba ọ̀na.
20. Ẹniti o si gbà irugbin lori apata, on li o gbọ́ ọ̀rọ na, ti o si fi ayọ̀ gbà a kánkan.
21. Ṣugbọn ko ni gbongbo ninu ara rẹ̀, o si pẹ diẹ li akokò kan; nigbati wahalà tabi inunibini si dide nitori ọ̀rọ na, lojukanna a kọsẹ̀.
22. Eyi pẹlu ti o gbà irugbin sarin ẹgún li ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ na; aniyan aiye yi, ati itanjẹ ọrọ̀ si fún ọ̀rọ na pa, bẹ̃li o si jẹ alaileso.
23. Ṣugbọn ẹniti o gbà irugbin si ilẹ rere li ẹniti o gbọ́ ọ̀rọ na, ti o si yé e; on li o si so eso pẹlu, o si so omiran ọgọrọrun, omiran ọgọtọta, omiran ọgbọgbọ̀n.
24. Owe miran li o pa fun wọn, wipe; Ijọba ọrun dabi ọkunrin ti o fún irugbin rere si oko rẹ̀:
25. Ṣugbọn nigbati enia sùn, ọtá rẹ̀ wá, o fún èpo sinu alikama, o si ba tirẹ̀ lọ.
26. Ṣugbọn nigbati ẽhu rẹ̀ sọ jade, ti o si so eso, nigbana li èpo buburu fi ara hàn pẹlu.
27. Bẹ̃li awọn ọmọ-ọdọ bãle na tọ̀ ọ wá, nwọn wi fun u pe, Oluwa, irugbin rere ki iwọ fún sinu oko rẹ? nibo li o ha ti li èpo buburu?
28. O si wi fun wọn pe, Ọtá li o ṣe eyi. Awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ si bi i pe, Iwọ ha fẹ́ ki a lọ fà wọn tu kuro?
29. O si wipe, Bẹ̃kọ, nigbati ẹnyin ba ntu èpo kuro, ki ẹnyin ki o má bà tu alikama pẹlu wọn.
30. Ẹ jẹ ki awọn mejeji ki o dàgba pọ̀ titi di igba ikorè: li akokò ikorè emi o si wi fun awọn olukore pe, Ẹ tètekọ kó èpo jọ, ki ẹ di wọn ni ití lati fi iná sun wọn, ṣugbọn ẹ kó alikama sinu abà mi.