1. LI ọjọ kanna ni Jesu ti ile jade, o si joko leti okun.
2. Ọpọlọpọ enia pejọ sọdọ rẹ̀, tobẹ̃ ti o fi bọ sinu ọkọ̀, o joko; gbogbo enia si duro leti okun.
3. O si fi owe ba wọn sọ̀rọ ohun pipọ, o wipe, Wo o, afunrugbin kan jade lọ lati funrugbin;
4. Bi o si ti nfún u, diẹ bọ́ si ẹba-ọ̀na, awọn ẹiyẹ si wá, nwọn si ṣà a jẹ.
5. Diẹ si bọ sori ilẹ apata, nibiti kò li erupẹ̀ pipọ; nwọn si sọ jade lọgan, nitoriti nwọn ko ni ijinlẹ;
6. Nigbati õrùn si goke, nwọn jona: nitoriti nwọn kò ni gbongbo, nwọn si gbẹ.