45. Nigbana li o lọ, o si mu ẹmi meje miran pẹlu ara rẹ̀, ti o buru jù on tikararẹ̀ lọ; nwọn bọ si inu rẹ̀, nwọn si ngbé ibẹ̀; igbẹhin ọkunrin na si buru jù iṣaju rẹ̀ lọ. Gẹgẹ bẹ̃ni yio ri fun iran buburu yi pẹlu.
46. Nigbati o nsọ̀rọ wọnyi fun awọn enia, wò o, iya rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀ duro lode, nwọn nfẹ ba a sọ̀rọ.
47. Nigbana li ẹnikan wi fun u pe, Wo o, iya rẹ ati awọn arakunrin rẹ duro lode, nwọn nfẹ ba ọ sọ̀rọ.
48. Ṣugbọn o dahùn o si wi fun ẹniti o sọ fun u pe, Tani iya mi? ati tani awọn arakunrin mi?
49. O si nà ọwọ́ rẹ̀ si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o wipe, Ẹ wò iya mi ati awọn arakunrin mi!
50. Nitori ẹnikẹni ti o ba nṣe ifẹ Baba mi ti mbẹ li ọrun, on na li arakunrin mi, ati arabinrin mi, ati iya mi.