Mat 12:1-2 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LAKOKÒ na ni Jesu là ãrin oko ọkà lọ li ọjọ isimi; ebi si npa awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, nwọn si bẹ̀rẹ si ima ya ipẹ́ ọkà, nwọn si njẹ.

2. Ṣugbọn nigbati awọn Farisi ri i, nwọn wi fun u pe, Wò o, awọn ọmọ-ẹhin rẹ nṣe eyi ti kò yẹ lati ṣe li ọjọ isimi.

Mat 12