9. Ani kili ẹnyin jade lọ iṣe? lati lọ iwò wolĩ? Lõtọ ni mo wi fun nyin, o si jù wolĩ lọ.
10. Nitori eyiyi li ẹniti a ti kọwe nitori rẹ̀ pe, Wò o, mo rán onṣẹ mi siwaju rẹ, ẹniti yio tún ọ̀na rẹ ṣe niwaju rẹ.
11. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ninu awọn ti a bí ninu obinrin, kò si ẹniti o ti idide jù Johanu Baptisti lọ; ṣugbọn ẹniti o kere julọ ni ijọba ọrun o pọ̀ ju u lọ.
12. Lati igba ọjọ Johanu Baptisti wá, titi o fi di isisiyi ni ijọba ọrun di ifi agbara wọ, awọn alagbara si fi ipá gbà a.
13. Nitori gbogbo awọn wolĩ ati ofin li o wi tẹlẹ ki Johanu ki o to de.
14. Bi ẹnyin o ba gbà a, eyi ni Elijah ti mbọ̀ wá.
15. Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́.
16. Ṣugbọn kili emi iba fi iran yi wé? O dabi awọn ọmọ kekeke ti njoko li ọjà ti nwọn si nkọ si awọn ẹgbẹ wọn,
17. Ti nwọn si nwipe, Awa fun fère fun nyin ẹnyin kò jó; awa si ṣọ̀fọ fun nyin, ẹnyin kò sọkun.
18. Nitori Johanu wá, kò jẹ, bẹ̃ni kò mu, nwọn si wipe, o li ẹmi èṣu.
19. Ọmọ-enia wá, o njẹ, o si nmu, nwọn wipe, Wò o, ọjẹun, ati ọmuti, ọrẹ́ awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ. Ṣugbọn a dare fun ọgbọ́n lati ọdọ awọn ọmọ rẹ̀ wá.