15. Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́.
16. Ṣugbọn kili emi iba fi iran yi wé? O dabi awọn ọmọ kekeke ti njoko li ọjà ti nwọn si nkọ si awọn ẹgbẹ wọn,
17. Ti nwọn si nwipe, Awa fun fère fun nyin ẹnyin kò jó; awa si ṣọ̀fọ fun nyin, ẹnyin kò sọkun.
18. Nitori Johanu wá, kò jẹ, bẹ̃ni kò mu, nwọn si wipe, o li ẹmi èṣu.
19. Ọmọ-enia wá, o njẹ, o si nmu, nwọn wipe, Wò o, ọjẹun, ati ọmuti, ọrẹ́ awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ. Ṣugbọn a dare fun ọgbọ́n lati ọdọ awọn ọmọ rẹ̀ wá.
20. Nigbana li o bẹ̀rẹ si iba ilu wọnni wi, nibiti o gbé ṣe ọ̀pọlọpọ iṣẹ agbara rẹ̀, nitoriti nwọn kò ronupiwada;
21. Egbé ni fun iwọ, Korasini! egbé ni fun iwọ, Betsaida! ibaṣepe a ti ṣe iṣẹ agbara ti a ṣe ninu nyin ni Tire on Sidoni, nwọn iba ti ronupiwada lailai ninu aṣọ ọ̀fọ ati ninu ẽru.
22. Ṣugbọn mo wi fun nyin, yio san fun Tire pẹlu Sidoni li ọjọ idajọ jù fun ẹnyin lọ.
23. Ati iwọ Kapernaumu, a o ha gbé ọ ga soke ọrun? a o rẹ̀ ọ silẹ si Ipo-oku: nitori ibaṣepe a ti ṣe iṣẹ agbara ti a ṣe ninu rẹ ninu Sodomu, on iba wà titi di oni.
24. Ṣugbọn mo wi fun nyin, yio san fun ilẹ Sodomu li ọjọ idajọ jù fun iwọ lọ.
25. Lakokò na ni Jesu dahùn, o si wipe, Mo dupẹ lọwọ rẹ Baba, Oluwa ọrun on aiye, nitoriti iwọ pa nkan wọnyi mọ́ kuro li oju awọn ọlọ́gbọn ati amoye, iwọ si fi wọn hàn fun awọn ọmọ-ọwọ́.
26. Gẹgẹ bẹ̃ na ni, Baba, nitori bẹ̀li o tọ́ li oju rẹ.
27. Ohun gbogbo li a fifun mi lati ọdọ Baba mi wá: kò si si ẹniti o mọ̀ Ọmọ, bikoṣe Baba; bẹ̃ni kò si ẹniti o mọ̀ Baba bikoṣe Ọmọ, ati ẹnikẹni ti Ọmọ fẹ fi i hàn fun.
28. Ẹ wá sọdọ mi gbogbo ẹnyin ti nṣiṣẹ́, ti a si di ẹrù wuwo le lori, emi o si fi isimi fun nyin.
29. Ẹ gbà àjaga mi si ọrùn nyin, ki ẹ si mã kọ́ ẹkọ́ lọdọ mi; nitori oninu tutu ati onirẹlẹ ọkan li emi; ẹnyin o si ri isimi fun ọkàn nyin.