Mat 11:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe, nigbati Jesu pari aṣẹ rẹ̀ tan fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mejejila, o ti ibẹ̀ rekọja lati ma kọni, ati lati ma wasu ni ilu wọn gbogbo.

2. Nigbati Johanu gburo iṣẹ Kristi ninu tubu, o rán awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ meji,

3. O si wipe, Iwọ li ẹniti mbọ̀, tabi ki a mã reti ẹlomiran?

4. Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ, ẹ si sọ ohun wọnyi ti ẹnyin gbọ́, ti ẹ si ri fun Johanu:

5. Awọn afọju nriran, awọn amukun si nrìn, a nwẹ̀ awọn adẹtẹ̀ mọ́, awọn aditi ngbọràn, a njí awọn okú dide, a si nwasu ihinrere fun awọn òtoṣi.

6. Alabukun-fun si li ẹnikẹni ti kì yio ri ohun ikọsẹ ninu mi.

Mat 11