5. Emi o si sunmọ nyin fun idajọ, emi o si ṣe ẹlẹri yiyara si awọn oṣó, ati si awọn panṣaga, ati si awọn abura eké, ati awọn ti o ni alagbaṣe lara ninu ọyà rẹ̀, ati opo, ati alainibaba, ati si ẹniti o nrẹ́ alejo jẹ, ti nwọn kò si bẹ̀ru mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
6. Nitori Emi li Oluwa, Emi kò yipada; nitorina li a kò ṣe run ẹnyin ọmọ Jakobu.
7. Lati ọjọ awọn baba nyin wá li ẹnyin tilẹ ti yapa kuro ni ilàna mi, ti ẹ kò si pa wọn mọ. Ẹ yipada si ọdọ mi, Emi o si yipada si ọdọ nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Ṣugbọn ẹnyin wipe, nipa bawo li awa o yipada?
8. Enia yio ha jà Ọlọrun li olè? ṣugbọn ẹnyin sa ti jà mi li olè. Ṣugbọn ẹnyin wipe, nipa bawo li awa fi jà ọ li olè? Nipa idamẹwa ati ọrẹ.
9. Riré li a o fi nyin ré: nitori ẹnyin ti jà mi li olè, ani gbogbo orilẹ-ède yi.