Mal 3:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. KIYESI i, Emi o rán onṣẹ mi, yio si tún ọ̀na ṣe niwaju mi: ati Oluwa, ti ẹnyin nwá, yio de li ojijì si tempili rẹ̀, ani onṣẹ majẹmu na, ti inu nyin dùn si; kiye si i, o mbọ̀ wá, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

2. Ṣugbọn tali o le gbà ọjọ wíwa rẹ̀? tani yio si duro nigbati o ba fi ara hàn? nitori on dabi iná ẹniti ndà fadakà, ati bi ọṣẹ afọṣọ:

3. On o si joko bi ẹniti nyọ́, ti o si ndà fadakà: yio si ṣe awọn ọmọ Lefi mọ́, yio si yọ́ wọn bi wurà on fadakà, ki nwọn ki o le mu ọrẹ ododo wá fun Oluwa.

4. Nigbana ni ọrẹ Juda ati ti Jerusalemu yio wù Oluwa, gẹgẹ bi ti ọjọ igbãni, ati gẹgẹ bi ọdun atijọ.

Mal 3