8. Ṣugbọn ẹnyin ti yapa kuro li ọ̀na na: ẹnyin ti mu ọ̀pọlọpọ kọsẹ ninu ofin; ẹnyin ti ba majẹmu Lefi jẹ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
9. Nitorina li emi pẹlu ṣe sọ nyin di ẹ̀gan, ati ẹni aikàsi niwaju gbogbo enia, niwọ̀n bi ẹnyin kò ti pa ọ̀na mi mọ, ti ẹnyin si ti nṣe ojusaju ninu ofin.
10. Baba kanna ki gbogbo wa ha ni? Ọlọrun kanna kó ha da wa bi? nitori kili awa ha ṣe nhùwa arekerekè olukuluku si arakunrin rẹ̀, nipa sisọ majẹmu awọn baba wa di alaimọ́.
11. Juda ti nhùwa arekerekè, a si ti nhùwa irira ni Israeli ati ni Jerusalemu: nitori Juda ti sọ ìwa mimọ́ Oluwa di alaimọ́, eyi ti o fẹ, o si ti gbe ọmọbinrin ọlọrun ajeji ni iyàwo.
12. Oluwa yio ke ọkunrin na ti o ṣe eyi kuro, olukọ ati ẹniti a nkọ, kuro ninu agọ Jakobu wọnni, ati ẹniti nrubọ ọrẹ si Oluwa awọn ọmọ-ogun.
13. Eyi li ẹnyin si tún ṣe, ẹnyin fi omije, ati ẹkún, ati igbe, bò pẹpẹ Oluwa mọlẹ, tobẹ̃ ti on kò fi kà ọrẹ nyin si mọ, tabi ki o fi inu-didùn gbà nkan lọwọ nyin.
14. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Nitori kini? Nitori Oluwa ti ṣe ẹlẹri lãrin iwọ ati lãrin aya ewe rẹ, ẹniti iwọ ti nhùwa ẹ̀tan si: bẹ̃li ẹgbẹ́ rẹ li on sa iṣe, ati aya majẹmu rẹ.