7. Nwọn si li ẹja kekeke diẹ: o si sure, o si ni ki a fi wọn siwaju wọn pẹlu.
8. Nwọn si jẹ, nwọn si yó: nwọn si kó ajẹkù ti o kù jọ agbọ̀n meje.
9. Awọn ti o jẹ ẹ to ìwọn ẹgbãji enia: o si rán wọn lọ.
10. Lojukanna, o si wọ̀ ọkọ̀ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si wá si apa ìha Dalmanuta.
11. Awọn Farisi si jade wá, nwọn bẹrẹ si bi i lẽre, nwọn nfẹ àmi lati ọrun wá lọwọ rẹ̀, nwọn ndán a wò.
12. O si kẹdùn gidigidi ninu ọkàn rẹ̀, o si wipe, Ẽṣe ti iran yi fi nwá àmi? lõtọ ni mo wi fun nyin, Ko si àmi ti a o fifun iran yi.
13. O si fi wọn silẹ o si tún bọ sinu ọkọ̀ rekọja lọ si apa ekeji.
14. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbagbé lati mu akara lọwọ, nwọn kò si ni jù iṣu akara kan ninu ọkọ̀ pẹlu wọn.
15. O si kìlọ fun wọn, wipe, Ẹ kiyesara, ki ẹ ma ṣọra nitori iwukara awọn Farisi ati iwukara Herodu.