Mak 8:20-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Ati nigba iṣu akara meje larin ẹgbaji enia, agbọ̀n melo li o kún fun ajẹkù ti ẹnyin kójọ? Nwọn si wipe, Meje.

21. O si wi fun wọn pe, Ẽha ti ṣe ti kò fi yé nyin?

22. O si wá si Betsaida; nwọn si mu afọju kan wá sọdọ rẹ̀, nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o fi ọwọ́ kàn a.

23. O si mu afọju na li ọwọ́, o si fà a jade lọ sẹhin ilu; nigbati o si tutọ́ si i loju, ti o si gbé ọwọ́ rẹ̀ le e, o bi i lẽre bi o ri ohunkohun.

24. O si wòke, o si wipe, Mo ri awọn enia dabi igi, nwọn nrìn.

25. Lẹhin eyini o si tún fi ọwọ́ kàn a loju, o si mu ki o wòke: o si sàn, o si ri gbogbo enia gbangba.

Mak 8