Mak 8:14-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbagbé lati mu akara lọwọ, nwọn kò si ni jù iṣu akara kan ninu ọkọ̀ pẹlu wọn.

15. O si kìlọ fun wọn, wipe, Ẹ kiyesara, ki ẹ ma ṣọra nitori iwukara awọn Farisi ati iwukara Herodu.

16. Nwọn si mba ara wọn ṣe aroye, wipe, Nitoriti awa kò mu akara lọwọ ni.

17. Nigbati Jesu si mọ̀, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣàroye pe ẹnyin ko ni akara lọwọ? ẹnyin ko ti ikiyesi titi di isisiyi, ẹ ko si ti iwoye, ẹnyin si li ọkàn lile titi di isisiyi?

18. Ẹnyin li oju ẹnyin kò si riran? ẹnyin li etí, ẹnyin kò si gbọran? ẹnyin kò si ranti?

19. Nigbati mo bu iṣu akara marun larin ẹgbẹdọgbọn enia, agbọ̀n melo li o kún fun ajẹkù ti ẹnyin kójọ? Nwọn si wi fun u pe, Mejila.

20. Ati nigba iṣu akara meje larin ẹgbaji enia, agbọ̀n melo li o kún fun ajẹkù ti ẹnyin kójọ? Nwọn si wipe, Meje.

Mak 8