Mak 8:10-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Lojukanna, o si wọ̀ ọkọ̀ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si wá si apa ìha Dalmanuta.

11. Awọn Farisi si jade wá, nwọn bẹrẹ si bi i lẽre, nwọn nfẹ àmi lati ọrun wá lọwọ rẹ̀, nwọn ndán a wò.

12. O si kẹdùn gidigidi ninu ọkàn rẹ̀, o si wipe, Ẽṣe ti iran yi fi nwá àmi? lõtọ ni mo wi fun nyin, Ko si àmi ti a o fifun iran yi.

13. O si fi wọn silẹ o si tún bọ sinu ọkọ̀ rekọja lọ si apa ekeji.

14. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbagbé lati mu akara lọwọ, nwọn kò si ni jù iṣu akara kan ninu ọkọ̀ pẹlu wọn.

Mak 8