43. Nwọn si kó agbọ̀n mejila kún fun ajẹkù, ati ti ẹja pẹlu.
44. Awọn ti o si jẹ ìṣu akara na to iwọn ẹgbẹdọgbọn ọkunrin.
45. Lojukanna li o si rọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati bọ sinu ọkọ̀, ki nwọn ki o si ṣiwaju lọ si apa keji si Betsaida, nigbati on tikararẹ̀ tú awọn enia ká.
46. Nigbati o si rán wọn lọ tan, o gùn ori òke lọ igbadura.
47. Nigbati alẹ si lẹ, ọkọ̀ si wà larin okun, on nikan si wà ni ilẹ.
48. O si ri nwọn nṣiṣẹ ni wiwà ọkọ̀; nitoriti afẹfẹ ṣe ọwọ òdi si wọn: nigbati o si di ìwọn iṣọ kẹrin oru, o tọ̀ wọn wá, o nrìn lori okun, on si nfẹ ré wọn kọja.
49. Ṣugbọn nigbati nwọn ri ti o nrìn loju omi, nwọn ṣebi iwin ni, nwọn si kigbe soke:
50. Nitori gbogbo wọn li o ri i, ti ẹ̀ru si ba wọn. Ṣugbọn lojukanna o si ba wọn sọ̀rọ, o si wi fun wọn pe, Ẹ tújuka: Emi ni; ẹ má bẹ̀ru.
51. O si wọ̀ inu ọkọ̀ tọ̀ wọn lọ; afẹfẹ si da: ẹ̀ru si ba wọn rekọja gidigidi ninu ara wọn, ẹnu si yà wọn.
52. Nwọn kò sá ronu iṣẹ iyanu ti iṣu akara: nitoriti ọkàn wọn le.
53. Nigbati nwọn si rekọja tan, nwọn de ilẹ awọn ara Genesareti, nwọn si sunmọ eti ilẹ.