Mak 6:43-45 Yorùbá Bibeli (YCE)

43. Nwọn si kó agbọ̀n mejila kún fun ajẹkù, ati ti ẹja pẹlu.

44. Awọn ti o si jẹ ìṣu akara na to iwọn ẹgbẹdọgbọn ọkunrin.

45. Lojukanna li o si rọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati bọ sinu ọkọ̀, ki nwọn ki o si ṣiwaju lọ si apa keji si Betsaida, nigbati on tikararẹ̀ tú awọn enia ká.

Mak 6