4. Ṣugbọn Jesu wi fun wọn pe, Ko si woli ti o wà laili ọlá, bikoṣe ni ilu on tikararẹ̀, ati larin awọn ibatan rẹ̀, ati ninu ile rẹ̀.
5. On ko si le ṣe iṣẹ agbara kan nibẹ̀, jù pe o gbé ọwọ́ rẹ̀ le awọn alaisan diẹ, o si mu wọn larada.
6. Ẹnu si yà a nitori aigbagbọ́ wọn. O si lọ si gbogbo iletò yiká, o nkọni.
7. O si pè awọn mejila na sọdọ rẹ̀, o bẹ̀rẹ si irán wọn lọ ni meji-meji; o si fi aṣẹ fun wọn lori awọn ẹmi aimọ́;
8. O si paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe mu ohunkohun, lọ si àjo wọn, bikoṣe ọpá nikan; ki nwọn ki o máṣe mu àpo, tabi akara, tabi owo ninu asuwọn wọn:
9. Ṣugbọn ki nwọn ki o wọ̀ salubàta: ki nwọn máṣe wọ̀ ẹ̀wu meji.
10. O si wi fun wọn pe, Nibikibi ti ẹnyin ba wọ̀ ile kan, nibẹ̀ ni ki ẹ mã gbé titi ẹnyin o fi jade kuro nibẹ̀ na.
11. Ẹnikẹni ti kò ba si gbà nyin, ti kò si gbọrọ̀ nyin, nigbati ẹnyin ba jade kuro nibẹ̀, ẹ gbọ̀n eruku ẹsẹ nyin fun ẹrí si wọn. Lõtọ ni mo wi fun nyin, yio san fun Sodomu ati Gomorra li ọjọ idajọ jù fun ilu nla na lọ.
12. Nwọn si jade lọ, nwọn si wasu ki awọn enia ki o le ronupiwada.