7. O si nkigbe li ohùn rara, wipe, Kini ṣe temi tirẹ, Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun Ọgá-ogo? mo fi Ọlọrun bẹ̀ ọ, ki iwọ ki o máṣe da mi loró.
8. Nitoriti o wi fun u pe, Jade kuro lara ọkunrin na, iwọ ẹmi aimọ́.
9. O si bi i lẽre pe, Orukọ rẹ? O si dahùn, wipe, Legioni li orukọ mi: nitori awa pọ̀.
10. O si bẹ̀ ẹ gidigidi pe, ki o máṣe rán wọn jade kuro ni ilẹ na.
11. Agbo ọ̀pọ ẹlẹdẹ kan si wà nibẹ ti njẹ lẹba oke.
12. Gbogbo awọn ẹmi èṣu bẹ̀ ẹ wipe, Rán wa lọ sinu awọn ẹlẹdẹ, ki awa ki o le wọ̀ inu wọn lọ.
13. Lọgan Jesu si jọwọ wọn. Awọn ẹmi aimọ́ si jade, nwọn si wọ̀ inu awọn ẹlẹdẹ lọ: agbo ẹlẹdẹ si tupũ nwọn si sure ni gẹrẹgẹrẹ lọ sinu okun (nwọn si to ìwọn ẹgbã;) nwọn si kú sinu okun.