14. Awọn ti mbọ́ wọn si sá, nwọn si lọ ròhin ni ilu nla, atì ni ilẹ na. Nwọn si jade lọ lati wò ohun na ti o ṣe.
15. Nwọn si wá sọdọ Jesu, nwọn si ri ẹniti o ti ni ẹmi èṣu, ti o si ni Legioni na, o joko, o si wọṣọ, iyè rẹ̀ si bọ si ipò: ẹ̀ru si ba wọn.
16. Awọn ti o ri i si ròhin fun wọn bi o ti ri fun ẹniti o li ẹmi èṣu, ati ti awọn ẹlẹdẹ pẹlu.
17. Nwọn si bẹ̀rẹ si ibẹ̀ ẹ, wipe, ki o lọ kuro li àgbegbe wọn.
18. Bi o si ti nwọ̀ inu ọkọ̀, ẹniti o ti li ẹmi èṣu na o mbẹ ẹ, ki on ki o le mã bá a gbé.
19. Ṣugbọn Jesu kò gbà fun u, ṣugbọn o wi fun u pe, Lọ si ile rẹ ki o si sọ fun awọn ará ile rẹ, bi Oluwa ti ṣe ohun nla fun ọ, ati bi o si ti ṣanu fun ọ.
20. O si pada lọ, o bẹ̀rẹ si ima ròhin ni Dekapoli, ohun nla ti Jesu ṣe fun u: ẹnu si yà gbogbo enia.
21. Nigbati Jesu si tun ti inu ọkọ̀ kọja si apa keji, ọ̀pọ enia pejọ tì i: o si wà leti okun.
22. Si wo o, ọkan ninu awọn olori sinagogu, ti a npè ni Jairu, wa sọdọ rẹ̀; nigbati o si ri i, o wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀,
23. O si bẹ̀ ẹ gidigidi, wipe, Ọmọbinrin mi kekere wà loju ikú: mo bẹ̀ ọ ki o wá fi ọwọ́ rẹ le e, ki a le mu u larada: on o si yè.
24. O si ba a lọ; ọ̀pọ enia si ntọ̀ ọ lẹhin, nwọn si nhá a li àye.
25. Obinrin kan ti o ti ni isun ẹ̀jẹ li ọdún mejila,
26. Ẹniti oju rẹ̀ si ri ohun pipọ lọdọ ọ̀pọ awọn oniṣegun, ti o si ti ná ohun gbogbo ti o ni tan, ti kò si sàn rara, ṣugbọn kàka bẹ̃ o npọ̀ siwaju.
27. Nigbati o gburo Jesu, o wá sẹhin rẹ̀ larin ọ̀pọ enia, o fọwọ́kàn aṣọ rẹ̀.