Mak 4:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si tún bẹ̀rẹ si ikọni leti okun: ọ̀pọ ijọ enia si pejọ sọdọ rẹ̀, tobẹ̃ ti o bọ́ sinu ọkọ̀ kan, o si joko ninu okun; gbogbo awọn enia si wà ni ilẹ leti okun.

2. O si fi owe kọ́ wọn li ohun pipọ, o si wi fun wọn ninu ẹkọ́ rẹ̀ pe,

3. Ẹ fi eti silẹ; Wo o, afunrugbin kan jade lọ ifunrugbin;

Mak 4