5. Ṣugbọn Jesu ko da a ni gbolohùn kan: tobẹ̃ ti ẹnu fi yà Pilatu.
6. Njẹ nigba ajọ na, on a ma dá ondè kan silẹ fun wọn, ẹnikẹni ti nwọn ba bere.
7. Ẹnikan si wà ti a npè ni Barabba, ẹniti a sọ sinu tubu pẹlu awọn ti o ṣọ̀tẹ pẹlu rẹ̀, awọn ẹniti o si pania pẹlu ninu ìṣọtẹ na.
8. Ijọ enia si bẹ̀rẹ si ikigbe soke li ohùn rara, nwọn nfẹ ki o ṣe bi on ti ima ṣe fun wọn ri.
9. Ṣugbọn Pilatu da wọn lohùn, wipe, Ẹnyin nfẹ ki emi ki o da Ọba awọn Ju silẹ fun nyin?
10. On sá ti mọ̀ pe nitori ilara ni awọn olori alufa ṣe fi i le on lọwọ.
11. Ṣugbọn awọn olori alufa rú awọn enia soke pe, ki o kuku dá Barabba silẹ fun wọn.
12. Pilatu si dahùn o tún wi fun wọn pe, Kili ẹnyin ha nfẹ ki emi ki o ṣe si ẹniti ẹnyin npè li Ọba awọn Ju?
13. Nwọn si tún kigbe soke, wipe, Kàn a mọ agbelebu.
14. Nigbana ni Pilatu si bi wọn lẽre, wipe, Eṣe? buburu kili o ṣe? Nwọn si kigbe soke gidigidi, wipe, Kàn a mọ agbelebu.
15. Pilatu si nfẹ se eyi ti o wù awọn enia, o da Barabba silẹ fun wọn. Nigbati o si nà Jesu tan, o fà a le wọn lọwọ lati kàn a mọ agbelebu.
16. Awọn ọmọ-ogun si fà a jade lọ sinu gbọ̀ngan, ti a npè ni Pretorioni; nwọn si pè gbogbo ẹgbẹ awọn ọmọ-ogun jọ.
17. Nwọn si fi aṣọ elesè àluko wọ̀ ọ, nwọn hun ade ẹgún, nwọn si fi dé e li ori;
18. Nwọn si bẹ̀rẹ si ikí i, wipe, Kabiyesi, Ọba awọn Ju!
19. Nwọn si fi ọpá iye lù u lori, nwọn si tutọ́ si i lara, nwọn si kunlẹ niwaju rẹ̀, nwọn si foribalẹ fun u.