3. Awọn olori alufa si fi i sùn li ohun pipọ: ṣugbọn on ko dahùn kan.
4. Pilatu si tún bi i lẽre, wipe, Iwọ ko dahùn ohun kan? wò ọ̀pọ ohun ti nwọn njẹri si ọ.
5. Ṣugbọn Jesu ko da a ni gbolohùn kan: tobẹ̃ ti ẹnu fi yà Pilatu.
6. Njẹ nigba ajọ na, on a ma dá ondè kan silẹ fun wọn, ẹnikẹni ti nwọn ba bere.
7. Ẹnikan si wà ti a npè ni Barabba, ẹniti a sọ sinu tubu pẹlu awọn ti o ṣọ̀tẹ pẹlu rẹ̀, awọn ẹniti o si pania pẹlu ninu ìṣọtẹ na.
8. Ijọ enia si bẹ̀rẹ si ikigbe soke li ohùn rara, nwọn nfẹ ki o ṣe bi on ti ima ṣe fun wọn ri.
9. Ṣugbọn Pilatu da wọn lohùn, wipe, Ẹnyin nfẹ ki emi ki o da Ọba awọn Ju silẹ fun nyin?
10. On sá ti mọ̀ pe nitori ilara ni awọn olori alufa ṣe fi i le on lọwọ.
11. Ṣugbọn awọn olori alufa rú awọn enia soke pe, ki o kuku dá Barabba silẹ fun wọn.
12. Pilatu si dahùn o tún wi fun wọn pe, Kili ẹnyin ha nfẹ ki emi ki o ṣe si ẹniti ẹnyin npè li Ọba awọn Ju?
13. Nwọn si tún kigbe soke, wipe, Kàn a mọ agbelebu.