10. On sá ti mọ̀ pe nitori ilara ni awọn olori alufa ṣe fi i le on lọwọ.
11. Ṣugbọn awọn olori alufa rú awọn enia soke pe, ki o kuku dá Barabba silẹ fun wọn.
12. Pilatu si dahùn o tún wi fun wọn pe, Kili ẹnyin ha nfẹ ki emi ki o ṣe si ẹniti ẹnyin npè li Ọba awọn Ju?
13. Nwọn si tún kigbe soke, wipe, Kàn a mọ agbelebu.
14. Nigbana ni Pilatu si bi wọn lẽre, wipe, Eṣe? buburu kili o ṣe? Nwọn si kigbe soke gidigidi, wipe, Kàn a mọ agbelebu.
15. Pilatu si nfẹ se eyi ti o wù awọn enia, o da Barabba silẹ fun wọn. Nigbati o si nà Jesu tan, o fà a le wọn lọwọ lati kàn a mọ agbelebu.