70. O si tún sẹ́. O si pẹ diẹ, awọn ti o duro nibẹ̀ tún wi fun Peteru pe, Lõtọ ni, ọkan ninu wọn ni iwọ iṣe: nitoripe ara Galili ni iwọ, ède rẹ si jọ bẹ̃.
71. Ṣugbọn o bẹ̀rẹ si iré ati si ibura, wipe, Emi ko mọ̀ ọkunrin yi ẹniti ẹnyin nwi.
72. Lojukanna akukọ si kọ lẹrinkeji. Peteru si ranti ọrọ ti Jesu wi fun u pe, Ki akukọ ki o to kọ lẹrinmeji, iwo o sẹ́ mi lẹrinmẹta. Nigbati o si rò o, o sọkun.