5. Jesu si da wọn lohùn, o bẹ̀rẹ si isọ fun wọn pẹ, Ẹ mã kiyesara, ki ẹnikẹni ki o máṣe tàn nyin jẹ:
6. Nitori awọn enia pipọ yio wá li orukọ mi, wipe, Emi ni Kristi; nwọn o si tàn ọ̀pọlọpọ jẹ.
7. Nigbati ẹnyin ba si ngburó ogun ati idagìri ogun; ki ẹnyin ki o máṣe jaiya: nitori irú nkan wọnyi kò le ṣe ki o ma ṣẹ; ṣugbọn opin na kì iṣe isisiyi.
8. Nitoripe orilẹ-ède yio dide si orilẹ-ede, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: isẹlẹ yio si wà ni ibi pupọ, ìyan yio si wà ati wahalà: nkan wọnyi ni ipilẹṣẹ ipọnju.
9. Ṣugbọn ẹ mã kiyesara nyin: nitori nwọn ó si fi nyin le awọn igbimọ lọwọ; a o si lù nyin ninu sinagogu: a o si mu nyin duro niwaju awọn balẹ ati awọn ọba nitori orukọ mi, fun ẹrí si wọn.
10. A kò le ṣaima kọ́ wasu ihinrere ni gbogbo orilẹ-ède.
11. Ṣugbọn nigbati nwọn ba nfà nyin, lọ, ti nwọn ba si nfi nyin le wọn lọwọ, ẹ maṣe ṣaniyan ṣaju ohun ti ẹ o sọ; ṣugbọn ohun ti a ba fifun nyin ni wakati na, on ni ki ẹnyin ki o wi: nitori kì iṣe ẹnyin ni nwi, bikoṣe Ẹmí Mimọ́.
12. Arakunrin yio si fi arakunrin fun pipa, ati baba yio fi ọmọ rẹ̀ hàn; awọn ọmọ yio si dide si obi wọn, nwọn o si mu ki a pa wọn.
13. Gbogbo enia ni yio si korira nyin nitori orukọ mi: ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na li a o gbalà.
14. Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba ri irira isọdahoro nì, ti o duro nibiti ko tọ́, ti a ti ẹnu woli Danieli ṣọ, (ẹnikẹni ti o ba kà a, ki o yé e,) nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea sálọ si ori òke: