39. Ati ibujoko ọlá ninu sinagogu, ati ipò ọla ni ibi ase;
40. Awọn ti o jẹ ile awọn opó run, ti nwọn si ngbadura gigun fun aṣehàn: awọn wọnyi ni yio jẹbi pọ̀ju.
41. Jesu si joko kọjusi apoti iṣura, o si nwò bi ijọ enia ti nsọ owo sinu apoti iṣura: ọ̀pọ awọn ọlọrọ̀ si sọ pipọ si i.
42. Talakà opó kan si wá, o sọ owo idẹ wẹ́wẹ meji ti iṣe idameji owo-bàba kan sinu rẹ̀.
43. O si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin pe, Talakà opó yi sọ sinu apoti iṣura jù gbogbo awọn ti o sọ sinu rẹ̀ lọ.
44. Nitori gbogbo nwọn sọ sinu rẹ̀ ninu ọ̀pọlọpọ ini wọn; ṣugbọn on ninu aini rẹ̀ o sọ ohun gbogbo ti o ni si i, ani gbogbo ini rẹ̀.