18. Awọn akọwe ati awọn olori alufa si gbọ́, nwọn si nwá ọ̀na bi nwọn o ti ṣe pa a run: nitori nwọn bẹ̀ru rẹ̀, nitori ẹnu yà gbogbo ijọ enia si ẹkọ́ rẹ̀.
19. Nigbati alẹ ba si lẹ, a jade kuro ni ilu.
20. Bi nwọn si ti nkọja lọ li owurọ, nwọn ri igi ọpọtọ na gbẹ ti gbongbo ti gbongbo.
21. Peteru si wa iranti o wi fun u pe, Rabbi, wò bi igi ọpọtọ ti iwọ fi bú ti gbẹ.
22. Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Ẹ ni igbagbọ́ si Ọlọrun.
23. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba wi fun òke yi pe, Ṣidi, ki o si bọ sinu okun; ti kò ba si ṣiyemeji li ọkàn rẹ̀, ṣugbọn ti o ba gbagbọ́ pe ohun ti on wi yio ṣẹ, yio ri bẹ̃ fun u.
24. Nitorina mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba tọrọ nigbati ẹ ba ngbadura, ẹ gbagbọ́ pe ẹ ti ri wọn gbà na, yio si ri bẹ̃ fun nyin.
25. Nigbati ẹnyin ba si duro ngbadura, ẹ darijì, bi ẹnyin ba ni ohunkohun si ẹnikẹni: ki Baba nyin ti mbẹ li ọrun ba le dari ẹṣẹ nyin jì nyin pẹlu.