Mak 10:31-37 Yorùbá Bibeli (YCE)

31. Ṣugbọn ọ̀pọ awọn ti o ṣiwaju ni yio kẹhin; awọn ti o kẹhin ni yio si ṣiwaju.

32. Nwọn si wà li ọ̀na nwọn ngoke lọ si Jerusalemu; Jesu si nlọ niwaju wọn: ẹnu si yà wọn; bi nwọn si ti ntọ̀ ọ lẹhin, ẹ̀ru ba wọn. O si tun mu awọn mejila, o bẹ̀rẹ si isọ gbogbo ohun ti a o ṣe si i fun wọn,

33. Wipe, Sá wo o, awa ngoke lọ si Jerusalemu, a o si fi Ọmọ-enia le awọn olori alufa, ati awọn akọwe lọwọ; nwọn o si da a lẹbi ikú, nwọn o si fi i le awọn Keferi lọwọ:

34. Nwọn o si fi i ṣe ẹlẹyà, nwọn o si nà a, nwọn o si tutọ́ si i lara, nwọn o si pa a: ni ijọ kẹta yio si jinde.

35. Jakọbu ati Johanu awọn ọmọ Sebede si wá sọdọ rẹ̀, wipe, Olukọni, awa nfẹ ki iwọ ki o ṣe ohunkohun ti awa ba bere lọwọ rẹ fun wa.

36. O si bi wọn lẽre pe, Kili ẹnyin nfẹ ki emi ki o ṣe fun nyin?

37. Nwọn si wi fun u pe, Fifun wa ki awa ki o le joko, ọkan li ọwọ́ ọtun rẹ, ati ọkan li ọwọ́ òsi rẹ, ninu ogo rẹ.

Mak 10