15. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti kò ba gbà ijọba Ọlọrun bi ọmọ kekere, kì yio le wọ̀ inu rẹ̀ bi o ti wù o ri.
16. O si gbé wọn si apa rẹ̀, o gbé ọwọ́ rẹ̀ le wọn, o si sure fun wọn.
17. Bi o si ti njade bọ̀ si ọ̀na, ẹnikan nsare tọ̀ ọ wá, o si kunlẹ fun u, o bi i lẽre, wipe, Olukọni rere, kili emi o ṣe ti emi o fi le jogún ìye ainipẹkun?
18. Jesu si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi npè mi li ẹni rere? ẹni rere kan ko si bikoṣe ẹnikan, eyini li Ọlọrun.
19. Iwọ sá mọ̀ ofin: Máṣe panṣaga, Máṣe pania, Máṣe jale, Máṣe jẹri eke, Máṣe rẹ-ni-jẹ, Bọwọ fun baba on iya rẹ.