14. Ṣugbọn nigbati Jesu ri i, inu bi i, o si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki awọn ọmọ kekere ki o wá sọdọ mi, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun: nitoriti irú wọn ni ijọba Ọlọrun.
15. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti kò ba gbà ijọba Ọlọrun bi ọmọ kekere, kì yio le wọ̀ inu rẹ̀ bi o ti wù o ri.
16. O si gbé wọn si apa rẹ̀, o gbé ọwọ́ rẹ̀ le wọn, o si sure fun wọn.
17. Bi o si ti njade bọ̀ si ọ̀na, ẹnikan nsare tọ̀ ọ wá, o si kunlẹ fun u, o bi i lẽre, wipe, Olukọni rere, kili emi o ṣe ti emi o fi le jogún ìye ainipẹkun?
18. Jesu si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi npè mi li ẹni rere? ẹni rere kan ko si bikoṣe ẹnikan, eyini li Ọlọrun.
19. Iwọ sá mọ̀ ofin: Máṣe panṣaga, Máṣe pania, Máṣe jale, Máṣe jẹri eke, Máṣe rẹ-ni-jẹ, Bọwọ fun baba on iya rẹ.
20. O si dahùn o si wi fun u pe, Olukọni, gbogbo nkan wọnyi li emi ti nkiyesi lati igba ewe mi wá.
21. Nigbana ni Jesu sì wò o, o fẹràn rẹ̀, o si wi fun u pe, Ohun kan li o kù ọ kù: lọ tà ohunkohun ti o ni ki o si fifun awọn talakà, iwọ ó si ni iṣura li ọrun: si wá, gbé agbelebu, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin.