16. Bi o si ti nrìn leti okun Galili, o ri Simoni ati Anderu arakunrin rẹ̀, nwọn nsọ àwọn sinu okun: nitoriti nwọn ṣe apẹja.
17. Jesu si wi fun wọn pe, Ẹ mã tọ̀ mi lẹhin, emi o si sọ nyin di apẹja enia.
18. Lojukanna nwọn si fi àwọn wọn silẹ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.
19. Bi o si ti lọ siwaju diẹ, o ri Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀, nwọn wà ninu ọkọ̀, nwọn ndí àwọn wọn.
20. Lojukanna o si pè wọn: nwọn si fi Sebede baba wọn silẹ ninu ọkọ̀ pẹlu awọn alagbaṣe, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.
21. Nwọn si lọ si Kapernaumu; lojukanna o si wọ̀ inu sinagogu li ọjọ, isimi, o si nkọ́ni.
22. Ẹnu si yà wọn si ẹkọ́ rẹ̀: nitoriti o nkọ́ wọn bi ẹniti o li aṣẹ, kì isi ṣe bí awọn akọwe.
23. Ọkunrin kan si wà ninu sinagogu wọn, ti o li ẹmi aimọ́; o si kigbe soke.
24. O wipe, Jọwọ wa jẹ; kini ṣe tawa tirẹ, Jesu ara Nasareti? iwọ wá lati pa wa run? emi mọ̀ ẹniti iwọ ṣe, Ẹni-Mimọ́ Ọlọrun.
25. Jesu si ba a wi, o wipe, Pa ẹnu rẹ mọ́, ki o si jade kuro lara rẹ̀.