Luk 9:48-59 Yorùbá Bibeli (YCE)

48. O si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ti o ba gbà ọmọde yi nitori orukọ mi, o gbà mi: ati ẹnikẹni ti o ba gbà mi, o gbà ẹniti o rán mi: nitori ẹniti o ba kere ju ninu gbogbo nyin, on na ni yio pọ̀.

49. Johanu si dahùn o si wi fun u pe, Olukọni, awa ri ẹnikan o nfi orukọ rẹ lé awọn ẹmi èṣu jade; awa si da a lẹkun, nitoriti kò ba wa tọ̀ ọ lẹhin.

50. Jesu si wi fun u pe, Máṣe da a lẹkun mọ́: nitori ẹniti kò ba lodi si wa, o wà fun wa.

51. O si ṣe, nigbati ọjọ atigbà soke rẹ̀ pé, o gbé oju le gangan lati lọ si Jerusalemu.

52. O si rán awọn onṣẹ lọ si iwaju rẹ̀: nigbati nwọn si lọ nwọn wọ̀ iletò kan ti iṣe ti ara Samaria lọ ipèse silẹ dè e.

53. Nwọn kò si gbà a, nitoriti oju rẹ̀ dabi ẹnipe o nlọ si Jerusalemu.

54. Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ Jakọbu on Johanu si ri i, nwọn ni, Oluwa, iwọ ko jẹ ki awa ki o pè iná lati ọrun wá, ki a sun wọn lúlu, bi Elijah ti ṣe?

55. Ṣugbọn Jesu yipada, o si ba wọn wi, o ni, Ẹnyin kò mọ̀ irú ẹmí ti mbẹ ninu nyin.

56. Nitori Ọmọ-enia ko wá lati pa ẹmi enia run, bikoṣe lati gbà a là. Nwọn si lọ si iletò miran.

57. O si ṣe, bi nwọn ti nlọ li ọ̀na, ọkunrin kan wi fun u pe, Oluwa, Emi nfẹ lati ma tọ̀ ọ lẹhin nibikibi ti iwọ ba nlọ.

58. Jesu si wi fun u pe, Awọn kọ̀lọkọlọ ni ihò, awọn ẹiyẹ oju ọrun si ni itẹ́; ṣugbọn Ọmọ-enia kò ni ibi ti yio fi ori rẹ̀ le.

59. O si wi fun ẹlomiran pe, Mã tọ̀ mi lẹhin. Ṣugbọn o wi fun u pe, Oluwa, jẹ ki emi ki o kọ́ lọ isinku baba mi na.

Luk 9