38. Si kiyesi i, ọkunrin kan ninu ijọ kigbe soke, wipe, Olukọni, mo bẹ̀ ọ, wò ọmọ mi; nitori ọmọ mi kanṣoṣo na ni.
39. Si kiyesi i, ẹmi èṣu a ma mu u, a si ma kigbe lojijì; a si ma nà a tàntàn titi yio fi yọ ifofó li ẹnu, a ma pa a lara, a tilẹ fẹrẹ má fi i silẹ lọ.
40. Mo si bẹ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ lati lé e jade; nwọn kò si le ṣe e.
41. Jesu si dahùn, wipe, Iran alaigbagbọ́ ati arekereke, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti ṣe sũru fun nyin pẹ to? Fà ọmọ rẹ wá nihinyi.
42. Bi o si ti mbọ̀, ẹmi èṣu na gbé e ṣanlẹ, o si nà a tantan. Jesu si ba ẹmi aimọ́ na wi, o si mu ọmọ na larada, o si fà a le baba rẹ̀ lọwọ.
43. Ẹnu si yà gbogbo wọn si iṣẹ ọlánla Ọlọrun. Ṣugbọn nigbati hà si nṣe gbogbo wọn si ohun gbogbo ti Jesu ṣe, o wi fun awon ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe,
44. Ẹ jẹ ki ọrọ wọnyi ki o rì si nyin li etí: nitori a o fi Ọmọ-enia le awọn enia lọwọ.
45. Ṣugbọn ọ̀rọ na ko yé wọn, o si ṣú wọn li oju, bẹ̃ni nwọn kò si mọ̀ ọ: ẹ̀ru si mba wọn lati bère idi ọ̀rọ na.
46. Iyan kan si dide lãrin wọn, niti ẹniti yio ṣe olori ninu wọn.
47. Nigbati Jesu si mọ̀ ìro ọkàn wọn, o mu ọmọde kan, o gbé e joko lọdọ rẹ̀,
48. O si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ti o ba gbà ọmọde yi nitori orukọ mi, o gbà mi: ati ẹnikẹni ti o ba gbà mi, o gbà ẹniti o rán mi: nitori ẹniti o ba kere ju ninu gbogbo nyin, on na ni yio pọ̀.