Luk 9:13-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ṣugbọn o wi fun wọn pe, Ẹ fi onjẹ fun wọn jẹ. Nwọn si wi fun u pe, Awa kò ni jù iṣu akara marun lọ, pẹlu ẹja meji; bikoṣepe awa lọ irà onjẹ fun gbogbo awọn enia wọnyi.

14. Nitori awọn ọkunrin to ìwọn ẹgbẹdọgbọn enia. O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, ki nwọn ki o mu wọn joko li ẹgbẹ-ẹgbẹ, li aradọta.

15. Nwọn si ṣe bẹ̃, nwọn si mu gbogbo wọn joko.

16. Nigbana li o mu iṣu akara marun, ati ẹja meji na, nigbati o gbé oju soke, o sure si i, o si bù u, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o gbé e kalẹ niwaju awọn enia.

17. Nwọn si jẹ, gbogbo wọn si yó: nwọn ṣà agbọ̀n mejila jọ ninu ajẹkù ti o kù fun wọn.

18. O si ṣe, nigbati o kù on nikan, o ngbadura, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wà lọdọ rẹ̀: o si bi wọn pe, Tali awọn enia nfi emi pè?

19. Nwọn si dahùn wipe, Johanu Baptisti; ṣugbọn ẹlomiran ni, Elijah ni; ati awọn ẹlomiran wipe, ọkan ninu awọn woli atijọ li o jinde.

20. O si bi wọn pe, Ṣugbọn tali ẹnyin nfi emi ipè? Peteru si dahùn, wipe, Kristi ti Ọlọrun.

21. O si kìlọ fun wọn, o si paṣẹ fun wọn, pe, ki nwọn ki o máṣe sọ ohun na fun ẹnikan.

22. O si wipe, Ọmọ-enia ko le ṣaima jìya ohun pipọ, a o si kọ̀ ọ lati ọdọ awọn àgbagba ati lati ọdọ awọn olori alufa, ati lati ọdọ awọn akọwe wá, a o si pa a, ni ijọ kẹta a o si ji i dide.

Luk 9