4. Bi o ti wọ̀ ile Ọlọrun lọ, ti o si mu akara ifihàn ti o jẹ, ti o si fifun awọn ti mbẹ lọdọ rẹ̀ pẹlu; ti kò yẹ fun u lati jẹ, bikoṣe fun awọn alufa nikanṣoṣo?
5. O si wi fun wọn pe, Ọmọ-enia li oluwa ọjọ isimi.
6. O si ṣe li ọjọ isimi miran, ti o wọ̀ inu sinagogu lọ, o si nkọ́ni: ọkunrin kan si mbẹ nibẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ ọtún rọ.
7. Ati awọn akọwe ati awọn Farisi nṣọ ọ, bi yio mu u larada li ọjọ isimi; ki nwọn ki o le ri ọna ati fi i sùn.
8. Ṣugbọn o mọ̀ ìro inu wọn, o si wi fun ọkunrin na ti ọwọ́ rẹ̀ rọ pe, Dide, ki o si duro lãrin. O si dide duro.
9. Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Emi o bi nyin lẽre ohunkan; O tọ́ lati mã ṣe ore li ọjọ isimi, tabi lati mã ṣe buburu? lati gbà ẹmí là, tabi lati pa a run?
10. Nigbati o si wò gbogbo wọn yiká, o wi fun ọkunrin na pe, Nà ọwọ́ rẹ. O si ṣe bẹ̃: ọwọ́ rẹ̀ si pada bọ̀ sipò gẹgẹ bi ekeji.
11. Nwọn si kún fun ibinu gbigbona; nwọn si ba ara wọn rò ohun ti awọn iba ṣe si Jesu.
12. O si ṣe ni ijọ wọnni, o lọ si ori òke lọ igbadura, o si fi gbogbo oru na gbadura si Ọlọrun.
13. Nigbati ilẹ si mọ́, o pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: ninu wọn li o si yàn mejila, ti o si sọ ni Aposteli;
14. Simoni, (ẹniti o si sọ ni Peteru,) ati Anderu arakunrin rẹ̀, Jakọbu ati Johanu, Filippi ati Bartolomeu,
15. Matiu ati Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Simoni ti a npè ni Selote,
16. Ati Juda arakunrin Jakọbu, ati Judasi Iskariotu ti iṣe onikupani.
17. O si ba wọn sọkalẹ, o si duro ni pẹ̀tẹlẹ, pẹlu ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ati ọ̀pọ ijọ enia, lati gbogbo Judea, ati Jerusalemu, ati àgbegbe Tire on Sidoni, ti nwọn wá lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, ati lati gbà dida ara kuro ninu arùn wọn;