15. Matiu ati Tomasi, Jakọbu ọmọ Alfeu, ati Simoni ti a npè ni Selote,
16. Ati Juda arakunrin Jakọbu, ati Judasi Iskariotu ti iṣe onikupani.
17. O si ba wọn sọkalẹ, o si duro ni pẹ̀tẹlẹ, pẹlu ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ati ọ̀pọ ijọ enia, lati gbogbo Judea, ati Jerusalemu, ati àgbegbe Tire on Sidoni, ti nwọn wá lati gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, ati lati gbà dida ara kuro ninu arùn wọn;
18. Ati awọn ti ara kan fun ẹmi aimọ́: a si mu wọn larada.
19. Gbogbo ijọ enia si nfẹ fi ọwọ́ kàn a; nitoriti aṣẹ njade lara rẹ̀, o si mu gbogbo wọn larada.
20. Nigbati o si gbé oju rẹ̀ soke si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o ni, Alabukun-fun li ẹnyin òtoṣi: nitori ti nyin ni ijọba Ọlọrun.
21. Alabukun-fun li ẹnyin ti ebi npa nisisiyi: nitoriti ẹ ó yo. Alabukun-fun li ẹnyin ti nsọkun nisisiyi: nitoriti ẹnyin ó rẹrin.
22. Alabukun-fun li ẹnyin, nigbati awọn enia ba korira nyin, ti nwọn ba yà nyin kuro ninu ẹgbẹ wọn, ti nwọn ba gàn nyin, ti nwọn ba ta orukọ nyin nù bi ohun buburu, nitori Ọmọ-enia.