32. Emi kò wá ipè awọn olododo, bikoṣe awọn ẹlẹṣẹ si ironupiwada.
33. Nwọn si bi i pe, Ẽṣe ti awọn ọmọ-ẹhin Johanu fi ngbàwẹ nigbakugba, ti nwọn a si ma gbadura, gẹgẹ bẹ̃ si ni awọn ọmọ-ẹhin awọn Farisi; ṣugbọn awọn tirẹ njẹ, nwọn nmu?
34. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin le mu ki awọn ọmọ ile iyawo gbàwẹ, nigbati ọkọ iyawo mbẹ lọdọ wọn?
35. Ṣugbọn ọjọ mbọ̀ nigbati a o gbà ọkọ iyawo lọwọ wọn, nigbana ni nwọn o si gbàwẹ ni ijọ wọnni.