Luk 5:18-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Sá si kiyesi i, awọn ọkunrin gbé ọkunrin kan ti o lẹ̀gba wá lori akete: nwọn nwá ọ̀na ati gbé e wọle, ati lati tẹ́ ẹ siwaju rẹ̀.

19. Nigbati nwọn kò si ri ọ̀na ti nwọn iba fi gbé e wọle nitori ijọ enia, nwọn gùn oke àja ile lọ, nwọn sọ̀ ọ kalẹ li alafo àja ti on ti akete rẹ̀ larin niwaju Jesu.

20. Nigbati o si ri igbagbọ́ wọn, o wi fun u pe, Ọkunrin yi, a dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ.

21. Awọn akọwe ati awọn Farisi bẹ̀rẹ si igberò, wipe, Tali eleyi ti nsọ ọrọ-odi? Tali o le dari ẹ̀ṣẹ jìni bikoṣe Ọlọrun nikanṣoṣo?

22. Ṣugbọn nigbati Jesu mọ̀ ìro inu wọn, o dahùn o si wi fun wọn pe, Kili ẹnyin nrò ninu ọkàn nyin?

23. Ewo li o ya jù, lati wipe, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ; tabi lati wipe, Dide ki iwọ ki o si mã rìn?

24. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe, Ọmọ-enia li agbara li aiye lati dari ẹ̀ṣẹ jìni, (o wi fun ẹlẹgba na pe,) Mo wi fun ọ, Dide, si gbé akete rẹ, ki o si lọ si ile rẹ.

25. O si dide lọgan niwaju wọn, o gbé ohun ti o dubulẹ le, o si lọ si ile rẹ̀, o nyìn Ọlọrun logo.

Luk 5