Luk 3:12-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Awọn agbowode si tọ̀ ọ wá lati baptisi lọdọ rẹ̀, nwọn si bi i pe, Olukọni, kili awa o ha ṣe?

13. O si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe fi agbara gbà jù bi a ti rán nyin lọ mọ́.

14. Awọn ọmọ-ogun si bère lọdọ rẹ̀, pe, Ati awa, kili awa o ṣe? O si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe huwa ipá si ẹnikẹni, ki ẹ má si ṣe rẹ ẹnikẹni jẹ; ki owo onjẹ nyin to nyin.

15. Bi awọn enia si ti nreti, ti gbogbo wọn si nrò ninu ara wọn nitori Johanu, bi on ni Kristi bi on kọ́;

16. Johanu dahùn o si wi fun gbogbo wọn pe, Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin; ṣugbọn ẹniti o lagbarà ju mi lọ mbọ̀, okùn bàta ẹsẹ ẹniti emi ko to itú: on ni yio fi Ẹmí Mimọ́ ati iná baptisi nyin:

17. Ẹniti atẹ rẹ̀ mbẹ li ọwọ́ rẹ̀, lati gbá ilẹ ipaka rẹ̀ mọ́ toto, ki o si kó alikama rẹ̀ sinu aká; ṣugbọn ìyangbo ni yio fi iná ajõku sun.

18. Ohun pipọ pẹlu li o si wasu fun awọn enia ni ọrọ iyanju rẹ̀.

19. Ṣugbọn Herodu tetrarki, ti o bawi nitori Herodia aya Filippi arakunrin rẹ̀, ati nitori ohun buburu gbogbo ti Herodu ti ṣe,

20. O fi eyi pari gbogbo rẹ̀ niti o fi Johanu sinu tubu.

21. Nigbati a si baptisi awọn enia gbogbo tan, o si ṣe, a baptisi Jesu pẹlu, bi o ti ngbadura, ọrun ṣí silẹ̀,

22. Ẹmí Mimọ́ si sọkalẹ si ori rẹ̀ li àwọ àdaba, ohùn kan si ti ọrun wá, ti o wipe, Iwọ ni ayanfẹ ọmọ mi; ẹniti inu mi dùn si gidigidi.

23. Jesu tikararẹ̀ nto bi ẹni ìwọn ọgbọ̀n ọdún, o jẹ (bi a ti fi pè) ọmọ Josefu, ti iṣe ọmọ Eli,

24. Ti iṣe ọmọ Mattati, ti iṣe ọmọ Lefi, ti iṣe ọmọ Melki, ti iṣe ọmọ Janna, ti iṣe ọmọ Josefu,

25. Ti iṣe ọmọ Mattatai, ti iṣe ọmọ Amosi, ti iṣe ọmọ Naumu, ti iṣe ọmọ Esli, ti iṣe ọmọ Naggai,

26. Ti iṣe ọmọ Maati, ti iṣe ọmọ Mattatia, ti iṣe ọmọ Simei, ti iṣe ọmọ Josefu, ti iṣe ọmọ Juda,

Luk 3