1. LI ọdún kẹdogun ijọba Tiberiu Kesari, nigbati Pontiu Pilatu jẹ Bãlẹ, Judea, ti Herodu si jẹ tetrarki Galili, Filippi arakunrin rẹ̀ si jẹ tetrarki Iturea ati ti Trakoniti, Lisania si jẹ tetrarki Abilene,
2. Ti Anna on Kaiafa nṣe olori awọn alufa, nigbana li ọ̀rọ Ọlọrun tọ̀ Johanu ọmọ Sakariah wá ni ijù.
3. O si wá si gbogbo ilẹ ìha Jordani, o nwasu baptismu ironupiwada fun imukuro ẹ̀ṣẹ;
4. Bi a ti kọ ọ ninu iwe ọ̀rọ woli Isaiah pe, Ohùn ẹni ti nkigbe ni ijù, Ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ẹ mu ipa-ọna rẹ̀ tọ́.
5. Gbogbo ọgbún li a o kún, gbogbo òke nla ati òke kekere li a o tẹ-bẹrẹ; wíwọ li a o ṣe ni títọ, ati ọ̀na palapala li a o sọ di kikuna;