32. Nwọn si ba ara wọn sọ pe, Ọkàn wa kò ha gbiná ninu wa, nigbati o mba wa sọ̀rọ li ọna, ati nigbati o ntumọ̀ iwe-mimọ́ fun wa?
33. Nwọn si dide ni wakati kanna, nwọn pada lọ si Jerusalemu, nwọn si ba awọn mọkanla pejọ, ati awọn ti mbẹ lọdọ wọn,
34. Nwipe, Oluwa jinde nitõtọ, o si ti fi ara hàn fun Simoni.
35. Nwọn si ròhin nkan ti o ṣe li ọ̀na, ati bi o ti di mimọ̀ fun wọn ni bibu àkara.
36. Bi nwọn si ti nsọ nkan wọnyi, Jesu tikararẹ̀ duro li arin wọn, o si wi fun wọn pe, Alafia fun nyin.
37. Ṣugbọn àiya fò wọn, nwọn si dijì, nwọn ṣebi awọn rí iwin.
38. O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ara nyin kò lelẹ̀? ẽsitiṣe ti ìrokuro fi nsọ ninu ọkàn nyin?
39. Ẹ wò ọwọ́ mi ati ẹsẹ mi, pe emi tikarami ni: ẹ dì mi mu ki ẹ wò o; nitoriti iwin kò li ẹran on egungun lara, bi ẹnyin ti ri ti mo ni.
40. Nigbati o si wi bẹ̃ tán, o fi ọwọ́ on ẹsẹ rẹ̀ hàn wọn.
41. Nigbati nwọn kò si tí igbagbọ́ fun ayọ̀, ati fun iyanu, o wi fun wọn pe, Ẹnyin ni ohunkohun jijẹ nihinyi?
42. Nwọn si fun u li ẹja bibu, ati afára oyin diẹ.