Luk 24:14-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Nwọn mba ara wọn sọ̀rọ gbogbo nkan wọnyi ti o ṣẹlẹ̀.

15. O si ṣe, nigbati nwọn mba ara wọn sọ, ti nwọn si mba ara wọn jirorò, Jesu tikararẹ̀ sunmọ wọn, o si mba wọn rìn lọ.

16. Ṣugbọn a rú wọn li oju ki nwọn ki o máṣe le mọ̀ ọ.

17. O si bi wọn pe, Ọ̀rọ kili ẹnyin mba ara nyin sọ, bi ẹnyin ti nrìn? Nwọn si duro jẹ, nwọn fajuro.

18. Ọkan ninu wọn, ti a npè ni Kleopa, si dahùn wi fun u pe, Alejò ṣá ni iwọ ni Jerusalemu, ti iwọ kò si mọ̀ ohun ti o ṣe nibẹ̀ li ọjọ wọnyi?

19. O si bi wọn pe, Kini? Nwọn si wi fun u pe, Niti Jesu ti Nasareti, ẹniti iṣe woli, ti o pọ̀ ni iṣẹ ati li ọ̀rọ niwaju Ọlọrun ati gbogbo enia:

20. Ati bi awọn olori alufa ati awọn alàgba wa ti fi i le wọn lọwọ lati da a lẹbi iku, ati bi nwọn ti kàn a mọ agbelebu.

21. Bẹ̃ni on li awa ti ni ireti pe, on ni iba da Israeli ni ìde. Ati pẹlu gbogbo nkan wọnyi, oni li o di ijọ kẹta ti nkan wọnyi ti ṣẹ.

22. Awọn obinrin kan pẹlu li ẹgbẹ wa, ti nwọn lọ si ibojì ni kutukutu, si wá idá wa nijì;

23. Nigbati nwọn kò si ri okú rẹ̀, nwọn wá wipe, awọn ri iran awọn angẹli ti nwọn wipe, o wà lãye.

24. Ati awọn kan ti nwọn wà pẹlu wa lọ si ibojì, nwọn si ri i gẹgẹ bi awọn obinrin ti wi: ṣugbọn on tikararẹ̀ ni nwọn kò ri.

Luk 24