51. (On kò ba wọn li ohùn ni ìmọ ati iṣe wọn), ara Arimatea, ilu awọn Ju kan, ẹniti on pẹlu nreti ijọba Ọlọrun;
52. Ọkunrin yi tọ̀ Pilatu lọ, o si tọrọ okú Jesu.
53. Nigbati o si sọ̀ ọ kalẹ, o si fi aṣọ àla dì i, o si tẹ́ ẹ sinu ibojì ti a gbẹ́ ninu okuta, nibiti a kò ti itẹ́ ẹnikẹni si ri.
54. O si ṣe ọjọ Ipalẹmọ: ọjọ isimi si kù si dẹ̀dẹ.
55. Ati awọn obinrin, ti nwọn bá a ti Galili wá, ti nwọn si tẹle, nwọn kiyesi ibojì na, ati bi a ti tẹ́ okú rẹ̀ si.
56. Nigbati nwọn si pada, nwọn pèse ohun olõrun didùn ororo ikunra ati turari tutù; nwọn si simi li ọjọ isimi gẹgẹ bi ofin.