Luk 23:16-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Njẹ emi ó nà a, emi ó si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ.

17. Ṣugbọn kò le ṣe aidá ọkan silẹ fun wọn nigba ajọ irekọja.

18. Nwọn si kigbe soke lọwọ kanna, wipe, Mu ọkunrin yi kuro, ki o si dá Barabba silẹ fun wa:

19. Ẹniti a sọ sinu tubu nitori ọ̀tẹ kan ti a ṣe ni ilu, ati nitori ipania.

20. Pilatu si tun ba wọn sọrọ, nitori o fẹ da Jesu silẹ.

21. Ṣugbọn nwọn kigbe, wipe, Kàn a mọ agbelebu, kàn a mọ agbelebu.

22. O si wi fun wọn li ẹrinkẹta pe, Ẽṣe, buburu kili ọkunrin yi ṣe? emi ko ri ọ̀ran ikú lara rẹ̀: nitorina emi o nà a, emi a si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ.

23. Nwọn tilẹ̀ kirimọ́ igbe nla, nwọn nfẹ ki a kàn a mọ agbelebu. Ohùn ti wọn ati ti awọn olori alufa bori tirẹ̀.

24. Pilatu si fi aṣẹ si i pe, ki o ri bi nwọn ti nfẹ.

25. O si dá ẹniti nwọn fẹ silẹ fun wọn, ẹniti a titori ọ̀tẹ ati ipania sọ sinu tubu; ṣugbọn o fi Jesu le wọn lọwọ.

26. Bi nwọn si ti nfà a lọ, nwọn mu ọkunrin kan, Simoni ara Kirene, ti o nti igberiko bọ̀, on ni nwọn si gbé agbelebu na le, ki o mã rù u bọ̀ tẹle Jesu.

27. Ijọ enia pipọ li o ntọ̀ ọ lẹhin, ati awọn obinrin, ti npohùnrere ẹkún, ti nwọn si nṣe idarò rẹ̀.

28. Ṣugbọn Jesu yiju pada si wọn, o si wipe, Ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, ẹ má sọkun fun mi, ṣugbọn ẹ sọkun fun ara nyin, ati fun awọn ọmọ nyin.

29. Nitori kiyesi i, ọjọ mbọ̀ li eyiti ẹnyin o wipe, Ibukun ni fun àgan, ati fun inu ti kò bímọ ri, ati fun ọmú ti kò funni mu ri.

30. Nigbana ni nwọn o bẹ̀rẹ si iwi fun awọn òke nla pe, Wó lù wa; ati fun awọn òke kekeke pe, Bò wa mọlẹ.

31. Nitori bi nwọn ba nṣe nkan wọnyi sara igi tutù, kili a o ṣe sara gbigbẹ?

32. Nwọn si fà awọn meji lọ pẹlu, awọn arufin, lati pa pẹlu rẹ̀.

33. Nigbati nwọn si de ibi ti a npè ni Agbari, nibẹ̀ ni nwọn gbé kàn a mọ agbelebu, ati awọn arufin na, ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ọkan li ọwọ́ òsi.

34. Jesu si wipe, Baba, darijì wọn; nitoriti nwọn kò mọ̀ ohun ti nwọn nṣe. Nwọn si pín aṣọ rẹ̀ lãrin ara wọn, nwọn di ìbo rẹ̀.

35. Awọn enia si duro nworan. Ati awọn ijoye pẹlu wọn, nwọn nyọ-ṣùti si i, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; ki o gbà ara rẹ̀ là, bi iba ṣe Kristi, ayanfẹ Ọlọrun.

36. Ati awọn ọmọ-ogun pẹlu nfi i ṣe ẹlẹyà, nwọn tọ̀ ọ wá, nwọn nfi ọti kikan fun u,

Luk 23