Luk 23:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. GBOGBO ijọ enia si dide, nwọn si fà a lọ si ọdọ Pilatu.

2. Nwọn si bẹ̀rẹ si ifi i sùn, wipe, Awa ri ọkunrin yi o nyi orilẹ-ede wa li ọkàn pada, o si nda wọn lẹkun lati san owode fun Kesari, o nwipe on tikara-on ni Kristi ọba.

3. Pilatu si bi i lẽre, wipe, Iwọ ha li ọba awọn Ju? O si da a lohùn wipe, Iwọ wi i.

4. Pilatu si wi fun awọn olori alufa ati fun ijọ enia pe, Emi kò ri ẹ̀ṣẹ lọwọ ọkunrin yi.

5. Nwọn si tubọ tẹnumọ ọ pe, O nrú awọn enia soke, o nkọ́ni ká gbogbo Judea, o bẹ̀rẹ lati Galili wá titi o fi de ihinyi.

6. Nigbati Pilatu gbọ́ orukọ Galili, o bère bi ọkunrin na iṣe ara Galili.

7. Nigbati o si mọ̀ pe ara ilẹ Herodu ni, o rán a si Herodu, ẹniti on tikararẹ̀ wà ni Jerusalemu li akokò na.

8. Nigbati Herodu si ri Jesu, o yọ̀ gidigidi: nitoriti o ti nfẹ ẹ ri pẹ́, o sa ti ngbọ́ ìhin pipọ nitori rẹ̀; o si tanmọ̃ ati ri ki iṣẹ iyanu diẹ ki o ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe.

9. O si bère ọ̀rọ pipọ lọwọ rẹ̀; ṣugbọn kò da a lohùn kanṣoṣo.

Luk 23