Luk 21:24-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Nwọn o si ti oju idà ṣubu, a o si dì wọn ni igbekun lọ si orilẹ-ède gbogbo: Jerusalemu yio si di itẹmọlẹ li ẹsẹ awọn Keferi, titi akoko awọn Keferi yio fi kún.

25. Àmi yio si wà li õrùn, ati li oṣupa, ati ni irawọ; ati lori ilẹ aiye idamu fun awọn orilẹ-ede nitori ipaiya ti ariwo;

26. Aiya awọn enia yio ma já fun ibẹru, ati fun ireti nkan wọnni ti mbọ̀ sori aiye: nitori awọn agbara ọrun li a o mì titi.

27. Nigbana ni nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara ati ogo nla.

28. Ṣugbọn nigbati nkan wọnyi ba bẹ̀rẹ si iṣẹ, njẹ ki ẹ wò òke, ki ẹ si gbé ori nyin soke; nitori idande nyin kù si dẹ̀dẹ.

29. O si pa owe kan fun wọn pe; Ẹ kiyesi igi ọpọtọ, ati si gbogbo igi;

30. Nigbati nwọn ba rúwe, ẹnyin ri i, ẹ si mọ̀ fun ara nyin pe, igba ẹ̀run kù fẹfẹ.

31. Gẹgẹ bẹ̃ na li ẹnyin, nigbati ẹnyin ba ri nkan wọnyi ti nṣẹ, ki ẹnyin ki o mọ̀ pe, ijọba Ọlọrun kù si dẹ̀dẹ.

32. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Iran yi ki yio rekọja, titi gbogbo nkan wọnyi yio fi ṣẹ.

33. Ọrun on aiye yio rekọja: ṣugbọn ọ̀rọ mi kì yio rekọja.

Luk 21